Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

1 Chronicles 7 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 The sons of Issachar were Tola, Puah, Jashub, and Shimron—four in all. Àwọn ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu àti Ṣimroni, mẹ́rin ni gbogbo rẹ̀.
2 Tola's sons: Uzzi, Rephaiah, Jeriel, Jahmai, Ibsam, and Shemuel—heads of their clans, mighty warriors in the line of Tola through their generations. In David's days their count was 22,600. Àwọn ọmọ Tola: Ussi, Refaiah, Jehieli, Jamai, Ibsamu àti Samuẹli olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dafidi, àwọn ìran ọmọ Tola tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀ta (22,600).
3 Uzzi's son: Izrahiah. Izrahiah's sons: Michael, Obadiah, Joel, Isshiah—five chiefs in all. Àwọn ọmọ, Ussi: Israhiah. Àwọn ọmọ Israhiah: Mikaeli, Obadiah, Joẹli àti Iṣiah. Gbogbo àwọn márààrún sì jẹ́ olóyè.
4 With them, by generations and family lines, were 36,000 troops for war, since they had many wives and children. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (36,000) tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó.
5 Their relatives, all Issachar's clans, were 87,000 mighty warriors, listed by genealogy. Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Isakari, bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínláàádọ́rin (87,000) ni gbogbo rẹ̀.
6 Three sons of Benjamin: Bela, Becher, and Jediael. Àwọn ọmọ mẹ́ta Benjamini: Bela, Bekeri àti Jediaeli.
7 Bela's sons: Ezbon, Uzzi, Uzziel, Jerimoth, and Iri—five family heads, mighty warriors. Their genealogy counted 22,034. Àwọn ọmọ Bela: Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (22,034) ènìyàn.
8 Becher's sons: Zemirah, Joash, Eliezer, Elioenai, Omri, Jeremoth, Abijah, Anathoth, and Alemeth—all sons of Becher. Àwọn ọmọ Bekeri: Semirahi, Joaṣi, Elieseri, Elioenai, Omri, Jeremoti, Abijah, Anatoti àti Alemeti. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Bekeri.
9 Their genealogical record, by their generations, listed the heads of their ancestral families and 20,200 mighty warriors. Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ó lé nígba (20,200) ọkùnrin alágbára.
10 Jediael's son was Bilhan; Bilhan's sons were Jeush, Benjamin, Ehud, Chenaanah, Zethan, Tarshish, and Ahishahar. Ọmọ Jediaeli: Bilhani. Àwọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi Benjamini, Ehudu, Kenaana, Setamu, Tarṣiṣi àti Ahiṣahari.
11 These were Jediael's sons, family heads, mighty warriors—17,200 fit for military service. Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé nígba (17,200) akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun.
12 Shuppim and Huppim were the descendants of Ir, and the Hushites the descendants of Aher. Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri.
13 The sons of Naphtali were Jahziel, Guni, Jezer, and Shallum—the descendants of Bilhah. Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha.
14 Manasseh's sons: Asriel, whom his Aramean concubine bore; she also bore Machir, father of Gilead. Àwọn ìran ọmọ Manase: Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi.
15 Machir took a wife from among the Huppites and Shuppim; his sister's name was Maacah. The second was named Zelophehad; he had only daughters. Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.
16 Machir's wife Maacah bore a son and named him Peresh; his brother was Sheresh; his sons were Ulam and Rakem. Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu.
17 The son of Ulam: Bedan. These were the sons of Gilead son of Machir, son of Manasseh. Ọmọ Ulamu: Bedani. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manase.
18 His sister Hammolecheth gave birth to Ishhod, Abiezer, and Mahlah. Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila.
19 The sons of Shemida were Ahian, Shechem, Likhi, and Aniam. Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́: Ahiani, Ṣekemu, Likki àti Aniamu.
20 Ephraim's sons: Shuthelah, his son Bered, his son Tahath, his son Eleadah, his son Tahath. Àwọn ìran ọmọ Efraimu: Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀, Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀. Tahati ọmọ rẹ̀
21 His son Zabad, his son Shuthelah. The men of Gath, born in that land, killed Ezer and Elead when they went down to take the Gathites' livestock. Sabadi ọmọ, rẹ̀, àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀. Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn
22 Their father Ephraim mourned for many days, and his relatives came to comfort him. Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú.
23 He slept with his wife; she conceived and bore a son he named Beriah, because tragedy had struck his household. Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.
24 His daughter was Sheerah, who built Lower and Upper Beth-horon as well as Uzzen-sheerah. Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú.
25 Rephah was his son, Resheph his son, Telah his son, Tahan his son, Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀, Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀,
26 Ladan his son, Ammihud his son, Elishama his son, Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀,
27 Nun his son, and Joshua his son. Nuni ọmọ rẹ̀ àti Joṣua ọmọ rẹ̀.
28 Their possessions and settlements: Bethel with its villages, Naaran eastward, Gezer westward with its villages, Shechem with its villages, and on to Ayyah with its villages. Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò.
29 Along the borders of Manasseh's sons: Beth-shean, Taanach, Megiddo, and Dor, with their villages. Joseph son of Israel's descendants lived there. Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.
30 The sons of Asher were Imnah, Ishvah, Ishvi, and Beriah; their sister was Serah. Àwọn ọmọ Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera.
31 The sons of Beriah were Heber and Malchiel, who was the father of Birzaith. Àwọn ọmọ Beriah: Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti.
32 Heber was the father of Japhlet, Shomer, and Hotham, and of their sister Shua. Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua.
33 The sons of Japhlet were Pasach, Bimhal, and Ashvath. These were the sons of Japhlet. Àwọn ọmọ Jafileti: Pasaki, Bimhali àti Asifati. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti.
34 The sons of Shemer were Ahi, Rohgah, Hubbah, and Aram. Àwọn ọmọ Ṣomeri: Ahi, Roga, Jahuba àti Aramu.
35 The sons of his brother Helem were Zophah, Imna, Shelesh, and Amal. Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu Sofahi, Imina, Ṣeleṣi àti Amali.
36 The sons of Zophah were Suah, Harnepher, Shual, Beri, Imrah, Àwọn ọmọ Sofahi: Sua, Haniferi, Ṣuali, Beri, Imra.
37 Bezer, Hod, Shamma, Shilshah, Ithran, and Beera. Beseri, Hodi, Ṣamma, Ṣilisa, Itrani àti Bera.
38 The sons of Jether were Jephunneh, Pispa, and Ara. Àwọn ọmọ Jeteri: Jefunne, Pisifa àti Ara.
39 The sons of Ulla were Arah, Hanniel, and Rizia. Àwọn ọmọ Ulla: Arah, Hannieli àti Resia.
40 All these were Asher's descendants: heads of families, choice men, mighty warriors, heads of chiefs. Their war-service genealogy: 26,000 men. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) ọkùnrin.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]