Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 27 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 Do not boast about tomorrow, for you do not know what a day may bring. Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.
2 Let someone else praise you, and not your own mouth; a stranger, and not your own lips. Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ, àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.
3 A stone is heavy and the sand a burden, but a fool's provocation is heavier than both. Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.
4 Wrath is cruel and anger is overwhelming, but who can stand before jealousy? Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?
5 Open rebuke is better than love that stays hidden. Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.
6 A friend's wounds are faithful, but an enemy's kisses are deceitful. Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.
7 A well-fed person tramples honeycomb, but to the hungry even what is bitter tastes sweet. Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8 A man who strays from his home is like a bird that strays from its nest. Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.
9 Oil and incense gladden the heart, and the sweetness of a friend comes from heartfelt counsel. Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.
10 Do not forsake your friend or your father's friend, and do not go to your brother's house when disaster strikes; better a neighbor nearby than a brother far off. Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀, má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.
11 Be wise, my son, and make my heart glad, so that I can answer anyone who taunts me. Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.
12 The prudent sees danger and takes cover, but the simple keep going and pay the price. Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.
13 Take the garment of one who puts up security for a stranger; hold it as collateral when he does so for a foreign woman. Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.
14 Whoever blesses his neighbor with a loud voice early in the morning, it will be taken as a curse. Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè.
15 A quarrelsome wife is like a constant dripping on a rainy day. Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
16 Restraining her is like restraining the wind, or grasping oil with the right hand. dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.
17 Iron sharpens iron, and one person sharpens another. Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.
18 Whoever tends a fig tree will eat its fruit, and whoever guards his master will be honored. Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀ ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.
19 As water reflects the face, so the heart reflects the person. Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.
20 The grave and Destruction are never satisfied, and a person's eyes are never satisfied. Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.
21 The crucible is for silver and the furnace for gold, and a person is tested by the praise he receives. Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà, ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.
22 Though you grind a fool in a mortar with a pestle, along with the grain, his foolishness will not leave him. Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.
23 Know well the condition of your flocks, and give careful attention to your herds. Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
24 For riches do not last forever, nor does a crown endure to every generation. nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.
25 When the grass is gone and the new growth appears and the mountain herbs are gathered, Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé
26 the lambs will provide your clothing, and the goats will provide the price of a field; àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.
27 and there will be enough goats' milk for your food, for the food of your household and to sustain your servant girls. Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]