Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 1 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 The proverbs of Solomon, son of David, king of Israel: Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.
2 To know wisdom and instruction, to understand words of insight, Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
3 to receive instruction in wise conduct, in righteousness, justice, and fairness, Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;
4 to give prudence to the simple, knowledge and discretion to the young, láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
5 let the wise also hear and increase in learning, and let the one who understands gain guidance, Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
6 to understand a proverb and a parable, the words of the wise and their riddles. Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe, àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.
7 The fear of our Father is the beginning of knowledge; fools despise wisdom and instruction. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.
8 Listen, my son, to your father's instruction, and don't turn away from your mother's teaching, Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
9 for they are a graceful garland for your head and pendants for your neck. Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.
10 My son, if sinners entice you, do not give in. Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.
11 If they say, "Come with us, let us lie in wait for blood, let us ambush the innocent without cause; Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;
12 like the grave let us swallow them alive, and whole, like those who go down to the pit; jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
13 we will find all kinds of precious goods, we will fill our houses with plunder; a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,
14 throw in your lot with us; we will all share one purse," da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”
15 my son, do not walk in the way with them; hold back your foot from their paths, ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn.
16 for their feet run to evil, and they hurry to shed blood. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
17 For a net spread out before any bird's eyes catches nothing; Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀, ní ojú ẹyẹ!
18 but these lie in wait for their own blood; they ambush their own lives. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn. Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà.
19 Such are the ways of everyone greedy for unjust gain; it takes away the life of its possessors. Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́; yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.
20 Wisdom cries aloud in the street; in the open squares she lifts her voice. Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;
21 At the head of the noisy streets she calls out; at the entrance of the city gates she speaks: láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:
22 "How long, simple ones, will you love being simple? How long will mockers delight in their mocking and fools hate knowledge? “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó? Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó? Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?
23 If you respond to my correction, I, Wisdom, will pour out my spirit on you; I will make my words known to you. Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni, ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.
24 Because I have called and you refused, I stretched out my hand and no one paid attention, Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,
25 and you ignored all my counsel and rejected all my correction, níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,
26 I also will laugh at your calamity; I will mock when terror overtakes you, Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín; èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.
27 when terror overtakes you like a storm and your calamity comes like a whirlwind, when distress and anguish come upon you. Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.
28 Then they will call on me, but I will not answer; they will seek me earnestly but will not find me, “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.
29 because they hated knowledge and did not choose the fear of our Father, Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.
30 they rejected my counsel and despised all my correction. Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,
31 So they will eat the fruit of their own way and have their fill of their own schemes. wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún.
32 For the waywardness of the simple will kill them, and the complacency of fools will destroy them; Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run;
33 but whoever listens to me will dwell secure and be at ease, without dread of disaster." ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]