Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Numbers 26 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 After the plague, our Father said to Moses and to Eleazar son of Aaron the priest, Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn Olúwa sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé,
2 "take a census of the whole Israelite community by ancestral house, everyone twenty and older able to serve in Israel's army." “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.”
3 Moses and Eleazar the priest spoke with them on the plains of Moab, by the Jordan across from Jericho: Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,
4 "Count the people twenty years old and up, as our Father commanded Moses." These were Israel's people who came from the land of Egypt: “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá.
5 Reuben, Israel's firstborn. Sons of Reuben: Hanoch, clan of the Hanochites; Pallu, clan of the Palluites, Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá, láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;
6 of Hezron, the clan of the Hezronites; of Carmi, the clan of the Carmites. ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni; ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.
7 These are the clans of the Reubenites; they numbered 43,730. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730).
8 The sons of Pallu: Eliab. Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu,
9 Eliab's sons: Nemuel, Dathan, and Abiram—the same Dathan and Abiram, community representatives who challenged Moses and Aaron in Korah's assembly, when they challenged our Father. àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.
10 The earth opened its mouth and swallowed them and Korah, when the company died and the fire consumed 250 men—they became a warning. Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin. Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.
11 But the sons of Korah did not die. Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.
12 Simeon's sons by clan: Nemuel's, the Nemuelite clan; Jamin's, the Jaminite clan; Jachin's, the Jachinite clan, Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini;
13 of Zerah, the clan of the Zerahites; of Shaul, the clan of the Shaulites. ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu.
14 These are the clans of the Simeonites: 22,200. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé igba (22,200) ọkùnrin.
15 Gad's sons by clan: Zephon's clan, the Zephonites; Haggi's clan, the Haggites; Shuni's clan, the Shunites, Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn: ti Sefoni, ìdílé Sefoni; ti Haggi, ìdílé Haggi; ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;
16 of Ozni, the clan of the Oznites; of Eri, the clan of the Erites; ti Osni, ìdílé Osni; ti Eri, ìdílé Eri;
17 of Arod, the clan of the Arodites; of Areli, the clan of the Arelites. ti Arodi, ìdílé Arodi; ti Areli, ìdílé Areli.
18 These are the clans of the sons of Gad as they were numbered: 40,500. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).
19 Judah's sons were Er and Onan; Er and Onan died in the land of Canaan. Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.
20 Judah's sons by clan: from Shelah, Shelanite clan; from Perez, Perezite clan; from Zerah, Zerahite clan. Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣela, ìdílé Ṣela; ti Peresi, ìdílé Peresi; ti Sera, ìdílé Sera.
21 Perez's sons: Hezron, clan of the Hezronites; Hamul, clan of the Hamulites. Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu.
22 These are the clans of Judah as they were numbered: 76,500. Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (76,500).
23 Issachar's sons by clan: Tola, clan of the Tolaites; Puvah, clan of the Punites, Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa;
24 of Jashub, the clan of the Jashubites; of Shimron, the clan of the Shimronites. ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.
25 These are the clans of Issachar as they were numbered: 64,300. Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (64,300).
26 Zebulun's sons by clan: from Sered, the Seredite clan; from Elon, the Elonite clan; from Jahleel, the Jahleelite clan. Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Seredi, ìdílé Seredi; ti Eloni, ìdílé Eloni; ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.
27 These are the clans of the Zebulunites as they were numbered: 60,500. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).
28 The sons of Joseph according to their clans were Manasseh and Ephraim. Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu.
29 Manasseh's sons: Machir's clan, the Machirites; Machir fathered Gilead; Gilead's clan, the Gileadites. Àwọn ọmọ Manase: ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi); ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.
30 Sons of Gilead: Iezer, clan of Iezerites; Helek, clan of Helekites, Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, ìdílé Ieseri; ti Heleki, ìdílé Heleki
31 and of Asriel, the clan of the Asrielites; and of Shechem, the clan of the Shechemites; àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli; àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;
32 and of Shemida, the clan of the Shemidaites; and of Hepher, the clan of the Hepherites. àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida; àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.
33 Zelophehad son of Hepher had no sons, only daughters: Mahlah, Noah, Hoglah, Milcah, and Tirzah. (Selofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).
34 These are the clans of Manasseh; they numbered 52,700. Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).
35 These are Ephraim's descendants by family: Shuthelah, family of the Shuthelahites; Becher, family of the Becherites; Tahan, family of the Tahanites. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi; ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri; ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.
36 And these are the sons of Shuthelah: of Eran, the clan of the Eranites. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi: ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani.
37 These are the clans of Ephraim's sons, by their count: 32,500. These are Joseph's sons by their clans. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
38 Benjamin's sons by clan: Bela, clan of the Belaites; Ashbel, clan of the Ashbelites; Ahiram, clan of the Ahiramites, Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;
39 of Shephupham, the clan of the Shuphamites; of Hupham, the clan of the Huphamites. ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.
40 Bela's sons: Ard and Naaman—from Ard, the Ardite clan; from Naaman, the Naamite clan. Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí: ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi; ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.
41 These are the sons of Benjamin by their clans; they numbered 45,600. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600).
42 These were Dan's sons by clan: from Shuham, the Shuhamite clan. These were Dan's clans by clan. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu. Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
43 All the clans of the Shuhamites numbered 64,400. Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé irinwó (64,400).
44 Asher's sons by clan: Imnah, clan of the Imnites; Ishvi, clan of the Ishvites; Beriah, clan of the Beriites. Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina; ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi; ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii.
45 Sons of Beriah: Heber, clan of Heberites; Malchiel, clan of Malchielites. Ti àwọn ọmọ Beriah: ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi; ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli.
46 Asher had a daughter named Serah. (Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.)
47 These are the clans of the sons of Asher as they were numbered: 53,400. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400).
48 Naphtali's sons by clan: Jahzeel, clan of Jahzeelites; Guni, clan of Gunites, Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni;
49 of Jezer, the clan of the Jezerites; of Shillem, the clan of the Shillemites. ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri; ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.
50 These are the clans of Naphtali; they numbered 45,400. Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbèje (45,400).
51 This was the total number of the people of Israel: 601,730. Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀sán dín làádọ́rin (601,730).
52 Then our Father said to Moses, Olúwa sọ fún Mose pé,
53 "Among these the land is to be divided for inheritance according to the number of names. “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn.
54 Give the larger group more land, the smaller less—each share sized to its census count. Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ.
55 But the land must be divided by lot; they will inherit according to their fathers' tribal names. Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í.
56 Their inheritance is to be apportioned by lot between the larger and the smaller." Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.”
57 These are the numbered Levites by their clans: Gershon's clan, the Gershonites; Kohath's clan, the Kohathites; Merari's clan, the Merarites. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.
58 Levi's clans: Libnite clan, Hebronite clan, Mahlite clan, Mushite clan, Korahite clan. Kohath fathered Amram. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu,
59 Amram's wife was named Jochebed, Levi's daughter, born to Levi in Egypt; she bore Amram Aaron, Moses, and their sister Miriam. orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu.
60 And to Aaron were born Nadab and Abihu, Eleazar and Ithamar. Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari.
61 But Nadab and Abihu died when they offered unauthorized fire before our Father. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)
62 The Levites counted numbered 23,000, every male a month old and up. They were not counted among the Israelites, since no inheritance was given them among the Israelites. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.
63 Moses and Eleazar the priest counted these on the plains of Moab by the Jordan, across from Jericho. Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko.
64 None of these had been counted by Moses and Aaron the priest in the wilderness of Sinai. Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai.
65 For our Father had said of them, "They would surely die in the wilderness." None remained, except Caleb son of Jephunneh and Joshua son of Nun. Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]