Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Luke 3 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 In Tiberius Caesar's fifteenth year, when Pontius Pilate was governor of Judea, Herod was tetrarch of Galilee, his brother Philip of the region of Ituraea and Trachonitis, and Lysanias of Abilene, Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,
2 under high priests Annas and Caiaphas, our Father's word came to John son of Zechariah in the wilderness. tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù.
3 He went through the whole Jordan region, preaching a baptism of repentance for the forgiveness of sins, Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀,
4 as it is written in the book of the words of Isaiah the prophet: "A voice of one calling in the wilderness: Prepare the way for the Lord, make his paths straight. bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé, “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
5 Every valley will be filled in, and every mountain and hill made low. The crooked roads will become straight, and the rough ways smooth, Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ. Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.
6 and all flesh will see the salvation of our Father." Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”
7 John said then to the crowds coming to be baptized by him: "You brood of vipers! Who warned you to flee the coming wrath? Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?
8 So produce fruit worthy of repentance. Don't start telling yourselves, 'We have Abraham as our father.' For I tell you, our Father can raise up children for Abraham from these stones. Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí.
9 Already the axe lies at the root of the trees; every tree not bearing good fruit is cut down and thrown into the fire." Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”
10 And the crowds asked him, "What then should we do?" Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”
11 He replied, "Whoever has two shirts, share with the one who has none; whoever has food, do the same." Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
12 Tax collectors also came to be baptized, and they said to him, "Teacher, what should we do?" Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
13 "Collect no more than you are required to," he told them. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
14 Soldiers also asked him, "And us—what should we do?" He said to them, "Don't extort anyone by force or false charges; be satisfied with your wages." Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
15 The people were expectant, all wondering in their hearts whether John himself might be the Christ. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́;
16 John answered them all, "I baptize you with water. But one stronger than I is coming—I'm not worthy to untie his sandal strap. He will baptize you with the Holy Spirit and fire. Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú, Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín.
17 Winnowing fork in hand, he will clear his threshing floor, gather the wheat into his barn, but burn the chaff with fire that can't be put out." Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”
18 And with many other words of exhortation, John proclaimed the good news to the people. Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìyìnrere fún wọn.
19 But John confronted Herod the tetrarch about Herodias, his brother's wife, and about all the evil Herod had done, Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe,
20 Herod added this to all the rest: he locked John up in prison. Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígbà tí ó fi Johanu sínú túbú.
21 When all the people were baptized, Jesus was baptized too. As he prayed, heaven opened, Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀,
22 and the Holy Spirit descended on him in bodily form like a dove. And a voice came from heaven: "You are my beloved Son; in you I delight." Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
23 Jesus was about thirty when he began his ministry, the son—so it was thought—of Joseph, son of Heli, Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Eli,
24 the son of Matthat, the son of Levi, the son of Melchi, the son of Jannai, the son of Joseph, tí í ṣe ọmọ Mattati, tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki, tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,
25 the son of Mattathias, the son of Amos, the son of Nahum, the son of Esli, the son of Naggai, tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi, tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili, tí í ṣe ọmọ Nagai,
26 the son of Maath, the son of Mattathias, the son of Semein, the son of Josech, the son of Joda, tí í ṣe ọmọ Maati, tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei, tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,
27 the son of Joanan, the son of Rhesa, the son of Zerubbabel, the son of Shealtiel, the son of Neri, tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa, tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli, tí í ṣe ọmọ Neri,
28 the son of Melchi, the son of Addi, the son of Cosam, the son of Elmadam, the son of Er, tí í ṣe ọmọ Meliki, tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu, tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,
29 the son of Joshua, the son of Eliezer, the son of Jorim, the son of Matthat, the son of Levi, tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri, tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati, tí í ṣe ọmọ Lefi,
30 the son of Simeon, the son of Judah, the son of Joseph, the son of Jonam, the son of Eliakim, tí í ṣe ọmọ Simeoni, tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,
31 the son of Melea, the son of Menna, the son of Mattatha, the son of Nathan, the son of David, tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna, tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani, tí í ṣe ọmọ Dafidi,
32 the son of Jesse, the son of Obed, the son of Boaz, the son of Salmon, the son of Nahshon, tí í ṣe ọmọ Jese, tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi, tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,
33 the son of Amminadab, the son of Admin, the son of Arni, the son of Hezron, the son of Perez, the son of Judah, tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu, tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi, tí í ṣe ọmọ Juda.
34 the son of Jacob, the son of Isaac, the son of Abraham, the son of Terah, the son of Nahor, Tí í ṣe ọmọ Jakọbu, tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu, tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,
35 the son of Serug, the son of Reu, the son of Peleg, the son of Eber, the son of Shelah, tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu, tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi, tí í ṣe ọmọ Ṣela.
36 the son of Cainan, the son of Arphaxad, the son of Shem, the son of Noah, the son of Lamech, Tí í ṣe ọmọ Kainani, tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu, tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,
37 the son of Methuselah, the son of Enoch, the son of Jared, the son of Mahalalel, the son of Cainan, tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku, tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli, tí í ṣe ọmọ Kainani.
38 the son of Enosh, the son of Seth, the son of Adam, the son of our Father. Tí í ṣe ọmọ Enosi, tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu, tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]