Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Lamentations 3 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 I am the man who has seen affliction under the rod of his wrath. Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
2 He has driven me away and made me walk in darkness without any light. Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.
3 Surely against me he turns his hand again and again, all day long. Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
4 He has worn away my flesh and my skin; he has broken my bones. Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
5 He has besieged me and surrounded me with bitterness and hardship. Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
6 He has made me dwell in darkness like those long dead. Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
7 He has walled me in so I cannot escape; he has weighed down my chains. Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
8 Even when I call out and cry for help, he shuts out my prayer. Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.
9 He has blocked my ways with cut stones; he has made my paths crooked. Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.
10 He is a bear lying in wait for me, a lion in hiding. Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.
11 He drove me off my path and tore me to pieces; he has made me desolate. Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.
12 He bent his bow and set me as the target for his arrow. Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
13 He drove the arrows of his quiver into my vitals. Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
14 I have become the laughingstock of all my people, their mocking song all day long. Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
15 He has filled me with bitterness; he has sated me with bitterness. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.
16 He has made my teeth grind on gravel, and made me cower in the dust. Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
17 My soul has lost all peace; I have forgotten what happiness is. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
18 So I say, "My endurance has perished, and so has my hope from our Father." Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”
19 Remember my affliction and my wandering, the bitterness and the gall! Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.
20 My soul continually remembers it and is bowed down within me. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21 But this I call to mind, and therefore I have hope: Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.
22 The covenant love of our Father never ceases; his mercies never come to an end; Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
23 they are new every morning; great is your faithfulness. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀.
24 "Our Father is all I need," says my soul, "therefore I will hope in him." Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
25 Our Father is good to those who wait for him, to the soul who seeks him. Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.
26 It is good to wait quietly for the salvation of our Father. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.
27 It is good for a man to bear the yoke in his youth. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.
28 Let him sit alone in silence when it is laid on him; Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.
29 let him put his mouth in the dust—there may yet be hope; Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.
30 let him give his cheek to the one who strikes, and be filled with insults. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
31 For the Sovereign Father will not abandon forever. Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
32 Though he causes grief, he will have compassion according to the abundance of his covenant love; Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33 for he does not willingly afflict or grieve people. Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
34 To crush underfoot all the prisoners of the earth, Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
35 to deny a man justice in the sight of the Most High, Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,
36 to deprive a man of justice in his case—the Sovereign Father does not approve. láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.
37 Who has spoken and it came to pass, unless the Sovereign Father has commanded it? Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
38 Is it not from the mouth of the Most High that both calamity and good come? Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá?
39 Why should a living man complain about the punishment for his sins? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?
40 Let us examine and test our ways, and return to our Father! Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ.
41 Let us lift up our hearts and our hands to our Father in heaven: Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,
42 "We have sinned and rebelled, and you have not forgiven. “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.
43 You have wrapped yourself in anger and pursued us, killing without pity; “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú.
44 you have wrapped yourself with a cloud so that no prayer can pass through. Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45 You have made us scum and refuse among the peoples. Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
46 All our enemies open their mouths against us; “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa.
47 panic and pitfall have come upon us, devastation and destruction." Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48 My eyes flow with streams of water over the destruction of my people. Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.
49 My eyes will flow without ceasing, without respite, Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi,
50 until our Father looks down and sees from heaven. títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
51 My eyes bring grief to my soul at the fate of all the daughters of my city. Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.
52 I have been hunted like a bird by those who were my enemies without cause; Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.
53 they flung me alive into a pit and cast stones on me; Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí.
54 water closed over my head; I said, "I am lost." Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.
55 I called on your name, my Father, from the depths of the pit; Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56 you heard my plea: "Do not turn a deaf ear to my cry for help!" Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57 You came near on the day I called on you; you said, "Do not fear!" O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”
58 You have taken up my cause, Sovereign Father; you have redeemed my life. Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
59 You have seen the wrong done to me, my Father; judge my cause. O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. Gba ẹjọ́ mi ró!
60 You have seen all their vengeance, all their plots against me. Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.
61 You have heard their taunts, my Father, all their plots against me, Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,
62 the lips and thoughts of my assailants against me all day long. ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́.
63 Watch their every move; I am the object of their mocking song. Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.
64 You will repay them, my Father, according to the work of their hands. Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
65 You will give them hardness of heart; your curse will be on them. Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré.
66 You will pursue them in anger and destroy them from under the heavens of our Father. Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run Olúwa.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]