Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Genesis 10 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 This is the account of Noah's sons—Shem, Ham, and Japheth. Sons were born to them after the flood. Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.
2 The sons of Japheth: Gomer, Magog, Madai, Javan, Tubal, Meshech, and Tiras. Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
3 The sons of Gomer: Ashkenaz, Riphath, and Togarmah. Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
4 The sons of Javan: Elishah, Tarshish, Kittim, and Rodanim. Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
5 From these the coastland peoples divided into their lands, each by language, clan, and nation. (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).
6 The sons of Ham: Cush, Mizraim, Put, and Canaan. Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani.
7 The sons of Cush: Seba, Havilah, Sabtah, Raamah, and Sabteca. The sons of Raamah: Sheba and Dedan. Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba àti Dedani.
8 Cush fathered Nimrod, who was the first mighty man on the earth. Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
9 He was a mighty hunter before God, so they say, "Like Nimrod, a mighty hunter before God." Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”
10 The beginning of his kingdom was Babel, Erech, Accad, and Calneh, in the land of Shinar. Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari.
11 From that land he went out to Assyria and built Nineveh, Rehoboth-Ir, Calah, Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala,
12 and Resen, between Nineveh and Calah; this is the great city. àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.
13 Mizraim fathered the Ludim, the Anamim, the Lehabim, the Naphtuhim, Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu.
14 the Pathrusim, the Casluhim (from whom the Philistines came), and the Caphtorim. Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
15 Canaan fathered Sidon his firstborn, and Heth, Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti.
16 and the Jebusites, the Amorites, the Girgashites, Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi,
17 the Hivites, the Arkites, the Sinites, àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini,
18 the Arvadites, the Zemarites, and the Hamathites. Afterward the clans of the Canaanites spread out. àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀.
19 Canaan's border ran from Sidon toward Gerar to Gaza, and toward Sodom, Gomorrah, Admah, and Zeboiim, to Lasha. Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa.
20 These are Ham's sons, by their clans, languages, lands, and nations. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
21 Children were also born to Shem, older brother of Japheth, father of all Eber's descendants. A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.
22 The sons of Shem: Elam, Asshur, Arphaxad, Lud, and Aram. Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.
23 The sons of Aram: Uz, Hul, Gether, and Mash. Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki.
24 Arphaxad fathered Shelah, and Shelah fathered Eber. Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi.
25 Eber had two sons: one named Peleg, for the earth was divided in his days, and his brother named Joktan. Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.
26 Joktan fathered Almodad, Sheleph, Hazarmaveth, Jerah, Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera.
27 Hadoram, Uzal, Diklah, Hadoramu, Usali, Dikla,
28 Obal, Abimael, Sheba, Obali, Abimaeli, Ṣeba.
29 Ophir, Havilah, and Jobab; all these were the sons of Joktan. Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.
30 Their territory extended from Mesha toward Sephar, to the hill country of the east. Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn.
31 These are Shem's sons, by their clans, languages, lands, and nations. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
32 These are the clans of Noah's sons, by their lines of descent, in their nations; from these the nations spread across the earth after the flood. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Noa gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀-èdè wọn. Ní ipasẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]