Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

1 Chronicles 24 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 These are the divisions of Aaron's sons. Aaron's sons: Nadab and Abihu, Eleazar and Ithamar. Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
2 Nadab and Abihu died before their father, leaving no sons; so Eleazar and Ithamar served as priests. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
3 David divided them with Zadok, Eleazar's descendant, and Ahimelech, Ithamar's descendant, by their appointed service order. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.
4 Eleazar's sons were found to have more leaders than Ithamar's, so they were divided: sixteen family heads for Eleazar's, eight for Ithamar's, by their families. A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari.
5 They divided them by lot, both alike, since officials of the sanctuary and officials of our Father came from the sons of Eleazar and the sons of Ithamar. Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.
6 Shemaiah son of Nethanel, a Levite scribe, wrote them before the king, the officials, Zadok the priest, Ahimelech son of Abiathar, and the heads of the priestly and Levite families—one family chosen for Eleazar, one for Ithamar. Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.
7 The first lot fell to Jehoiarib, the second to Jedaiah, Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu, èkejì sí Jedaiah,
8 the third to Harim, the fourth to Seorim, ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu, ẹ̀kẹrin sì ní Seorimu,
9 the fifth to Malchijah, the sixth to Mijamin, ẹ̀karùnún sì ni Malkiah, ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sì ni Mijamini,
10 the seventh to Hakkoz, the eighth to Abijah, èkeje sì ni Hakosi, ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí ni Abijah,
11 the ninth to Jeshua, the tenth to Shecaniah, ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua, ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,
12 the eleventh to Eliashib, the twelfth to Jakim, ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu, ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sì ni Jakimu,
13 the thirteenth to Huppah, the fourteenth to Jeshebeab, ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa, ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,
14 the fifteenth to Bilgah, the sixteenth to Immer, ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah, ẹ̀kẹrìndínlógún sì ni Immeri,
15 the seventeenth to Hezir, the eighteenth to Happizzez, ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri, èkejìdínlógún sì ni Hafisesi,
16 the nineteenth to Pethahiah, the twentieth to Jehezkel, ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah, ogún sì ni Jeheskeli,
17 the twenty-first to Jachin, the twenty-second to Gamul, ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,
18 the twenty-third to Delaiah, and the twenty-fourth to Maaziah. ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.
19 These were their appointed duties for serving in our Father's house, by the order Aaron their father gave them, as our Father of Israel had commanded him. Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.
20 The rest of Levi's sons: of Amram's sons, Shubael; of Shubael's sons, Jehdeiah. Ìyókù àwọn ọmọ Lefi. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubaeli; Jehdeiah.
21 Of Rehabiah: of the sons of Rehabiah, Isshiah the first. Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.
22 Of the Izharites, Shelomoth; of the sons of Shelomoth, Jahath. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti; láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.
23 The sons of Hebron: Jeriah the first, Amariah the second, Jahaziel the third, Jekameam the fourth. Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jahasieli ẹlẹ́ẹ̀kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́ẹ̀kẹrin.
24 The sons of Uzziel: Micah; of the sons of Micah, Shamir. Àwọn ọmọ Usieli: Mika; nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.
25 The brother of Micah: Isshiah; of the sons of Isshiah, Zechariah. Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi; nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.
26 The sons of Merari: Mahli and Mushi. The sons of Jaaziah: Beno. Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.
27 The sons of Merari through Jaaziah: Beno, Shoham, Zaccur, and Ibri. Àwọn ọmọ Merari. Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.
28 Of Mahli: Eleazar, who had no sons. Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.
29 Of Kish: the sons of Kish, Jerahmeel. Láti Kiṣi. Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.
30 The sons of Mushi: Mahli, Eder, and Jerimoth. These were the Levites by their families. Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti. Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
31 They too cast lots, like their relatives the sons of Aaron, before King David, Zadok, Ahimelech, and the heads of the priestly and Levite families—the head of each family the same as his younger brother. Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèké.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]